top of page

Mímu omi líló àti ìpara Róòbù kò pa kòkòro Kòrónà (èyí tí wón ń pè ní Kóvídì- oókàndílógún)

Dr Mrs Faith Ayobamidele Obafemi

Friday, 3 April 2020

Àrokò kan wà tí ó gbé àwon àlàyé tí kìí se òtító dání, eléyìí tí ó n so káàkíri gbogbo social media pee mímu omi líló, pèlúu ìpara Róòbù yí ò pa kòkòro Kòrónà (Kóvídì- oókàndílógún). Eléyí kìí se òtító. A ti se àyèwóo rè, a sì ti bóo lójú pé kìí se béè.Àrokò náa tí ó wà lóríi social media wípé:

"Jòwó, mo bèbè pé kí o má pa eléyìí móra, ó lè gba ayé òpòlopò là. Ó wà fún kòkòro Kòrónà. Àwon àmì àìsàn kòkòro Kòrónà niyìí: 1. Òfun gbígbe 2. Ikó gbígbe 3. Òfun jíjáje 4. Sísín àti ikó wíwú. Jòwó, tí o bá se àkíyèsí kokan níinú àwon àmì yìí ní araa re, tètè wá omi gbígbóná kí o sì fi ìpara Róòbù kun, kí o wá gbée mu. Nítorí pé kòkòrò náa ń gbé inúu òfun ènìyàn fún wákàtí méjìlá. Tí o kò bá yára tèlé ìgbìmò tí àwon olùwòsàn àgbáyé (WHO) fi sílè, ìgbà náa ni kòkòro Kòrónà náa yí ò rí ààyè àti agbára láti wo inú àgo araa re, nítorí lásìkò yen, yí ò ti re gbogbo araa re, o kò sì ní lèwà láyé kojáa òsè méjì lo lórí ilè alààyè mó."Àyèwo wa nìyí


Sé omi líló pèlú ìpara Róòbù ń se ànfàní kankan fín Kóvídì- oókàndílógún?

A máa ń lo ìpara Róòbù fún ìtura nígbà òtútù, imú tó dí, orí fífó pèlú ara ríro àti ara wíwó. Kò sí ìdánilójú kan kan pé mímu omi tóló àti Róòbù yí ò pa Kóvídì-oókàndílógún. Dípò èyí, ó lè jásí wàhálà ńlá níinú àgó ara.

Ìpara Róòbù kìí se fín mímu tàbí ká fi sí inú ihò imú. Òpòlopò ìpara Róòbù ní Méntóòlù, Káfúrà àti Methyl Salicylate. Tí a bá muú ní àpòjù, gbogbo àwon ògùn tó wà ní inú rè lè di májèlé nínú ara tí ó sì le pa àláfìa wa lára lópòlopò. Nígbà tí a bá gbée mì, ìpara Róòbù lè fa àìsàn tó léwu sáraà re, àti wípé lára àwon ògùn inú rè lè fa ikú tó bá pòjù ní inúu àgó ara.Tódá lórí àrokò yí, ìgbàgbóo wa ni wípé nígbà tí enikéni bá bèrè sí ní rí ààmì, eni béè lè sèsè kò àrùn náa ni. Sé òtító nìyí?

Nípa àsewádì tí wón gbé jáde ní Annals of Internal Medicine [5], lórí àpapò, àwon ààmì Kóvídì-oókàndílógún máa ń yè jáde léyìn ojó márùn. Àwárí naa síwájú fi hàn pé àwon èyàn métàdínlógorún àti àbò nínú ogórun tó ní àrun kòkòrò naa á rí àwon ààmì títíi ojó mókànlá àtàbò láti àsìkò tí wón kókó kó àrùn naa. Èyí fi hàn pé èyàn á bèrè síní rí àwon ààmì tí á fi hàn dájú pé eni naa ní i, èyí tó túmò sí pé eni naa á ní láti ti gbé pèlú kòkòrò naa lára fún ojó púpò.

Covid 19

Sé Kóvídì-oókàndílógún ń dúró nínú òfun tó wákàtí méjìlá?

Kò sí èrí tó dábàá wípé kòkòrò naa ń dúró nínú òfun fún wákàtí méjìlá. Kòkòrò naa ń gbé inú séèlì, kìí kàn jókòó sínúu òfun débi tí a lè fi omi líló sàán wálè. Alámòdájú Trudie Lang ní ilé èkó gíga Ósífòdù so wípé “kò sí ìlànà èkó oníye” tó lè se àtìleyìn fún imoran tó sopé èyàn lè fo kòkòrò naa láti inú òfun wálè síinú ikùn láti paá." [6].


Sé WHO fún wa ní ìmòràn kankan nínú àrokò tí kò so òtító naa?

Rárá! Wo ìlànà méje tí WHO fi sílè fún ìdènà ìtànkalè Kóvídì-oókàndílógún (https://youtu.be/8c_UJwLq8PI)


Dr Mrs Faith Ayobamidele Obafemi is a Veterinary Doctor and lecturer at the Faculty of Veterinary Medicine, University of Abuja. She was a Fulbright Research Fellow at the Department of Natural Sciences of the Bowie State University in Maryland, USA from August 2016 to May 2017 and currently working on her PhD. Her research interests include stress and ameliorating its effects on Physiology; cancer therapy and management; and infectious diseases that impact Physiology.


bottom of page