top of page

Jíjẹ 'Àwọn Ounjẹ Ìpìlẹ̀ (Álkálíìnì)' Kò Le Dáàbò Bò ọ́ Kúrò Níbi Ààrun Kòrónà

Translated by Royhaan Folarin FASLN

Tuesday, 7 April 2020

Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì káàkiri àgbáyé ṣe ńwá ìwòsàn àti àjẹsára fún ààrun kòrónà, bẹ́ẹ̀ni ìtànkálẹ̀ orísirísi àlàyé àrékérekè nípa àrùn náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ewu tó ga jùlọ tí a ní láti kojú nínú akitiyan káríayé ní ìlòdì si arun kòrónà (KOFID-19). Láìpẹ́ yìí, Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) lo gbólóhùn 'infodemiiki' láti júwe ìtànkálẹ àlàyé àrékérekè lórí ààrùn Kòrónà, nípasẹ àwọn ẹ̀rọ ayélujára àti àwọn gbàgede mìíràn. Èyí sì jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí wọ́n sọ pé ó léwu jù àjàkáyé-àrùn kòrónà fúnra rẹ̀ lọ.


Fún àpẹẹrẹ, mo gba ìfiránṣẹ́ kan tí o ntàn káàkiri nípasẹ̀WhatsApp tí o lọ báyìí:

“Èyí ni láti sọ fún gbogbo wa pé ìwọn 'pH' fún ọlọ́jẹ kòrónà a máa wà láàrin 5.5 si 8.5. Gbogbo ohun tí a nilò láti ṣe láti borí kòkòrò kòrónà, ni kí á máà jẹ àwọn oúnjẹ Ìpìlẹ̀(Álkálíìnì) ti pH rẹ̀ ju ti kòkòrò yìí lọ . Nínú àwọn oúnjẹ yìí ni: Lẹ́mọ́ọ́nù - ti pH rẹ̀ jẹ́9.9, Òrombó wẹ́wẹ́ - pH 8.2, píhà òyìnbó - pH 15.6, ata ilẹ̀ - pH 13.2, máńgò - pH 8.7, ọsàn òyìnbó (tanjariini) - pH 8.5, ọ̀pẹ òyìnbó - pH 12.7, Dandeliọnu - pH 22.7, ọsán - pH 9.2. Báwo ni óó ṣe mọ̀ pé o ní kòkòrò kòrónà lára? 1. Yíyún nínú ọ̀fun, 2. Ọ̀fun gbígbẹ, 3. Ikọ́ gbẹrẹfu. 4. Ìgbóná t'ó lágbára 5. Àìlemí dáadáa. Nitorinaa, tí o bá ṣe àkíyèsí àwọn ǹkan wọ̀nyí, yára mu omi'gbóná pẹ̀lú lẹ́mọ́ọ́nù, kí ọ sì muú. Máṣe tọ́jú àlàyé yìí sí ọ̀dọ̀ ara rẹ nìkan. Fi ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ẹbíìrẹ àti àwọn ọ̀rẹ́. Ọlọ́hun yóò bùkún ọ. Òṣùwọ̀n pH ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà wà láti 0 sí 14, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan ni ó sì máa ń ṣubú sí àárín ìwọ̀n yìí. Ohun tí pH rẹ ba kéré si 7.0 jẹ ekikan, nígbàti ohunkóhun tí ó wà lókè 7.0 jẹ́ ìpìlẹ̀, tàbí alkalini. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀Khan Akademi (ojú opo ẹkọ wẹẹbu kan tí Bill Gates jẹ́onigbọwọ rẹ) ti kọọ,́ pH le ju 14 tabi kéré ju 0 lọ, ṣùgbọ́n kìí ṣe láàrin àwọn ohun ọ̀gbìn tó n wù fúnra rẹ̀. Àwọn tí o wa ni ìta sàkání ìwọn 0 - 14 jẹ́ oun tí a ṣe nínú láàbu.”


Ìfiránṣẹ́ tí o wà lókè yí jẹ́  àlàyé àrékérekè kan tí wọ́n hun dáradára, tí ó sì burú débi wípé o le ṣe okùnfà kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn kọ èyíkéyìí àjẹsára tí wọ́n bá ṣelọpọ̀ láti kojúu ọlọjẹ náà.

Àhesọ yìí pe 'àwọn oúnjẹ alkalini' ní ipa ìdènà tàbí ìwòsàn ni ìkojúu KOFID-19 jẹ́ latara àìní ìmọ ìjìnlẹ̀ sáyẹnsì, ti ò sí súnmọ́ kí o kó ìpalára bá ṣíṣàwári àti mímú lò àwọn àjẹsára KOFID-19 nígbà tí wón bá ṣe àwárí rẹ̀. Pẹ̀lú pẹlú, nínú àtẹ̀jade Afrika Ṣẹk (Africa Check) tí ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù kẹta, ọdún 2020, àhesọ ọ̀rọ̀ yìí di kíkó dánú níbẹ̀.

Covid 19

Àlàyé pé kòkòrò kòrónà ní pH tirẹ lọ́tọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò bá ìmọ sáyẹnsì mu. Ó le fẹràn agbègbè tí pH rẹ̀ rí bákan. pH kàn jẹ́ ìwọ̀n kan tí a fií ńwọn iye àwọn ayọ́nsi aidrojin (tàbí protonsi) tí ó wà nínú ǹkan. Kò sì wulẹ̀ ṣeéṣe kí á rí òun t'o kéré sí 0 nítorí pé a ti wọn òdiwọ̀n ọ̀hún láti 0 si 14. Ohun ti pH rẹ̀ bá wà nítòsí òdo (0) ni à ńrí nínú ásíìdì tí ó kan (irúfẹ́ èyí ti o ńsun ǹkan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀). Nítorí náà, kò ṣeé ṣe láti ní ìyẹn nínú èyíkéyìí oúnjẹ, kódà pẹ̀lú èyítí a pè ní oúnjẹ tí ó ní kemikali nínú.


Tí píhà òyìnbó bá ní pH 15.6 bí a ti ṣe kàá nínú ìfiránṣẹ́ àrékérekè yìí, kò sí ẹnìkan tí yóò le dìímú, kí á tó wá sọ jíjẹ. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí a bá jẹ, ara wá ní ètò tó ga jù fún ṣíṣàtúnṣe pH ti inú rẹ̀ láti ìṣẹ́jú kan sí òmíràn, láti lè dáàbò bo àpòjù ekikan tàbí alkaliini. Gẹ́gẹ́ bí jíjẹun t'ódára ṣe ní ipa rere lórí àlàáfíà ara gbogbogbò, a kò nílò láti mú oúnjẹ kan pàtó fún pH abẹ́nú wa láti dọ́gba. Àwọn ara wa ti ní ìpèsè tẹ́lẹ láti dọ́gba ararẹ̀.


Abdulrazak Ibrahim PhD jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìsẹ̀dálè àwọn makromolikulu tó pàtàkì sí ìgbésí ayé (molikula baoloji) ní Ilé-ìwé gíga Ahmadu Bello, Zaria-Nigeria.


Royhaan Folarin FASLN jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti olùkọ́nípa ẹ̀yà ara ati ọpọlọ (Anatomi & Niurosayensi) ní Ilé-ìwé gíga Ọlábísí Ọnàbánjọ, Sagamu, Nigeria.


bottom of page