top of page

Ìmò Nípa Àìsàn Kòkòrò Àífójurí Kòrónà (COVID-19)

Abdulrahman Olagunju

Wednesday, 1 April 2020

KÍNI ÀRÙN KÒRÓNA?

Àwon olójè KÒRÓNA jé ebí olójè tí o ma n fa àìsàn èémí ní ara ènìyàn. O le jeyo bi òtútù òrìnrìn tàbí ààrùn èémí tio ni agbára.


Àràmàndà KÒRÓNA olójè yii jé titun nínú àwon olójè kòróna. Àràmàndà olójè yii ti o n fa àjàkálè àrùn lówólówó yi ni àwon alabojuto ètò ìlera ní gbogbo àgbáyé n pe ni SARS-CoV-2. Àìsàn tí o n faa ni a n pè ní Àrùn Kòrónà olójè 2019.


BÁWO NI KÒKÒRÒ OLÓJÈ YII SE N TÀNKÁLÈ?

Àrùn kòróna olójè 2019 le ràn láti ara enìkan sí enìkejì nípasè fífi ara kan eni tí o ti ni àrùn yi, tàbí nípasè fífi ara kó omi ti o ba èémí tàbí ikó eni tí o ni àrùn yii jáde. Ótún seése kí a ko àrùn yi ti a ba fi ara tàbí owó kan nnkan tí olójè yi le ti wà ni ara rè, tí a si fi owó naa ba ojú, imú tàbí enu. Sugbon èyí kii se onà kan gboogi tí àrùn yii filè tànkálè.


NÍBO NI ÀRÙN KÒKÒRÒ OLÓJÈ 2019 YI TI RÀN DE?

Títí di ojó kefà, osù keta, odún 2020, àwon èèyàn egbèrún lónà aadorun-un lé marun-un ni wón ti fi ìdí e múlè wípé wón ti kó àrùn yi àti wípé, egbeedogun irinwo o din mokandinlogun ònkà yii ni o ti ipasè arun oloje 2019 papò dà. Leyi tí o jépé òpò nínú to o jeri sí  jépé àwon to  ní àrùn yii wa ni orílè èdè Chínà, o ti ran de orile ede tí o to èjídínlaadorú-ùn.


KÍNI ÀWON ÀRÍSÀMÌ ÀRÙN YÌÍ?

Láfiwé sí àwon àìsàn atégùn miiran, àwon àmì àìsàn yii lee pèlú ibà, ikó, àti èémí kíkúrú. Àwon ènìyàn tóbá kó àrùn yìí lee maa ri àwon àmì bii ìnira, ìsokun nímú, òfun kíkorò àti àrùn àjàkálè bi ìgbé gbuuru.


Àwon àrísàmì lee bèrè si ni farahàn làti bii ojó kejì sí ojó kerìnlá tí ènìyàn bati kó àrùn yii. Àwon arúgbó àti àwon to ni àìsàn miiran bii àrùn okàn àti ìtò súgà súnmó kí won ri òpolopò ìnira àti àmì tóle miiran.


BÁWO NI O SE LEE DAABO BO ARA RE KÚRÒ NINU ÀRÙN OLÓJÈ YII?

Ìdáàbòbò tí o dára jù ni ki ènìyàn yera fún àrùn olójè yii. O lee se eleyi pelu títèlé àwon ìgbésè yii - gégé bi o se lee yera fun irúfé àwon àìsàn ategun miiran


1. Fo owó re pèlú ose àti omi ní òòrè kóòrè. Tí omi àti ose o ba sí pèlú re, o lee lo ìfowó òyìnbó èyí tí wón fi otí se.

2. Yera fún ìbásepò pélú àwon alaisan.

3. Yera fún fífi owó kan ojú, imú àti enu pèlú owó re tí kòbá sí ní fífò.

4. Fowó bo enu àti imú re pèlú ìgbón re tí o bá sín tàbí wúkó.

5. Tí ara re kò bá yá, dúró nílé re.

6. Tí o bá ní àrùn atégùn bii ikó, aso àwobomú kòtó sí o. Lo aso àwobomú nígbà tí o bá rí àmì bi ikó tàbí àrùn olójè Kòrónà (COVID-19).

Covid 19

KÍNI O LEE SE TÍ O BA FURA PÉ O TI KÓ ÀRÙN YÌÍ?

Àwon àrísàmì àrùn olójè yii súnmó àwon àìsàn atégùn, leyi to jékí o sòro láti se ìyàtò re sí okùnfà àwon àìsàn atégùn.

Tí o bá fura pe oti ko àrùn yii, bèèrè fún ìtójú kíákíá. Títí di ìgbà tí oo rí ìtójú, tèlé àwon ìgbésè yii láti dènà ìtànkálè àrùn yii.

1. Sóra fún jíjáde, kí o sí dúró nílé. Tí o bá se e se, dúró nínú yàrá òtò, kí o sí maa lo balùwè òtò.

2. Maa nu àwon nnkan tí o bá fowó kan òòrè kóòrè

3. Se àkíyèsí àwon àmí tí o n jeyo ní ara re dájú kí o le se alaye tótó fún àwon onímò ìlera


NJE ÌWÒSÀN TÀBÍ ÀJESÁRA KAN TIWÀ BÍ?

Lówólówó bayii, kò tii sí iwosan, òògùn tabi abéré àjesára fún àrùn olójè 2019. Àwon ti o bá ní ìkolù àrùn yii ní láti gba ìtójú ti o péye láti owó àwon alámojútó ìlera.


bottom of page